Ajoro omo oduduwa

Ajoro omo oduduwa NOT GORVERNMENTAL ORGANIZATION (N.G.O)

21/01/2026

IGBOMINA TI DA SI ORO TO KAN GBOGBO ILE YORUBA GBANGBAN.

22/12/2025

NOW READY...

*YORUBA RO'NU* (Apa kini)Lati owo Egbe AJORO OMO ODUDUWA (R)Bi a ba gbe ade le oba l'ori, nitori afefe yeye ko, nitori k...
22/12/2025

*YORUBA RO'NU*
(Apa kini)
Lati owo
Egbe AJORO OMO ODUDUWA
(R)

Bi a ba gbe ade le oba l'ori, nitori afefe yeye ko, nitori ki ilu ma baa baje ni, nitori kilu le baa tooro,Ani nitori ki ilu le baa rogbo lafi nfi obaa je,
Ko si ani-ani,oba to go'ro ye gbodo ro arojile ko too ma gbe igbese,
Idi pataki niyii ti mo fi pe gbogbo oba alade ni'le Yoruba si akiyesi pe,e maa roo kee too see, nitoripe bi eyin ko ba roo ki e too see,ilu yoo pada rii ro,bi ilu ba wa pada rii ro,yoo si maa dabi eni pe,apere oba ti gba abode fun ilu ni,

EKU ILE OOO,
EGBE AJORO OMO ODUDUWA lo nki Iran omo Yoruba ni'le l'oko l'odo leyin odi,
Akiyesi to se pataki ni mo fe pe Iran Yoruba si,
Paa-paa ilu oyo Alaafin ojo pa sekere mode omo atiba,bi enu ilu oyo ko ba waa ka Oro yii,ki gbogbo omo Yoruba ma woran o,

Ibeere si gbogbo omo Yoruba to ye ki a maa beere lowo Alaafin oyo Alayeluwa oba Abdul Akeem owo-ade(Elewu etu akoko)to wa lor'oye nipe...,
Se ija agba ati emi juo Iwo ko jumi logbe won wa si Ori ipo ni abi isokan ati tesiwaju Iran Yoruba lapapo?

Nitoripe gbogbo Ori ko nii sun Inu posi,ki basepe gbogbo Ori nii sun posi ni,iroko igi ki ba ti tan nigbo,eni ti ori ba yan,nii gun'le si ipo oba,kilo waa de,ti aja-n-gbila ajulo fe maa ta ere si ilu oyo lara,
Itesiwaju ilu oyo lo si ye ko je Alaafin oyo logun,

Ni kete t'oba ti g'or'oye ni aami ati ila kaka awa lagba ti nf'araahan,
Eyii si nbi idojuti fun gbogbo Iran Yoruba lapapo, nitoripe ote to fi oju han n ni Awon obaa wa ni'le Yoruba gbe ka'ri,

Fun bi apeere,Oro oye ti Ooni risa,Oba Eniitan ogunwusi(ojaja keji) fi da oloye Dotun Sanusi Alase ilaji lola,gege bi Okanlomo Oodua,bi a ba ni ki a woo,

1-Oloye Dotun Sanusi Alase ilaji,to si iru oye bee latari ati maa se boo re laarin ilu fun igbega ati itesiwaju Ile Yoruba lapapo, opolopo ara ilu lo ti je Anfaani eni ti an so yii.

2-Ooni risa Oba Eniitan Adeoye Ogunwusi to lati fi eni to ba to je oye ninu ojulowo omo Yoruba fun idagba s'oke Ile wa.

3-Eni taa ba pe ni arole oduduwa ti wa ni ipo Alase ati asiwaju fun gbogbo oba to ku nile yoruba
ti ko si ye kari eyikeyii ninu ojulowo omo oko ninu awon omo oduduwa lati gboo lenu ni gba ti ko ba ti tapa si Ori apere awon baba nlaa wa,ti ko si gbabode fun Iran Yoruba

4-Lowo lowo,ipo alaga awon lobaloba Lorile ede naijiria ni Oonirisa wa.

Ki a ka die ki a dake,
Pelu awon idi pataki ti a yan-na-na si oke yii,ko ye ki ikun sinu kankan waye fun igbese ti Kabiesi Oonirisa oba Eniitan adeyeye Ogunwusi gbe lati fi oloye Dotun Sanusi Alase ilaji je oye OKANLOMO OODUA,

Kayeefi Oro to gba igboro,to si nse Oni kaluku ni haa-hin ni ikede to jade si igboro Laipe yii pe..

Alayeluwa oba Abdul Akeem owo-ade Elewu etu akoko naa fee fi omo aare orile edee wa yii tii se ogbeni Seyi tinuubu naa je oye OKANLOMO ILE YORUBA

Ibeere ti awon omo oko Ile Yoruba n bi araa won ni pe..

1-O se je pe OKANLOMO naa tun ni oye ti Alaafin oyo tun fee fi je,nigba ti a ti ni oye okan l'omo kan ti Oonirisa sese ja'we le l'ori ni kope kope yii?

2-Kinni atise-bo omo aare wa(Seyi tinuubu),ipa wo ni o ti ko fun idagba s'oke asa ati ise Ile Yoruba ki Alaafin oyo to ronu oye yii kan-an?

3-Bi ko ba si ote,ti ko si si dukuhu,
Kinni iyato ti afee fayo ni nu oye OKANLOMO ILE YORUBA ati OKANLOMO OODUA ?

4-Kinni Alaafin oyo fee gba ninu ifi'ga gba'ga ati ija agba to nba Oonirisaa fa?
E je ka se enu ni Deedee sibi na.

E waa je ka wo'nu itan Nipa Ile Yoruba ki a le pe gbogbo awon to ti sonu pada wale pe.."omo t'o so'le nu so apo iya ko"
E maa bami kalo..

ODUDUWA ni Iran Yoruba gbagbo gege bii baba-nla won,
eleyii ti Orirun gbogbo Iran Yoruba lapapo si je ilu ILE IFE,
Lara awon abikeyin omo fun oduduwa ni oranmiyan to lo te ilu oyo duro,
Adehun ebun ti awon egbon oranmiyan tiwon joo je omo baba se fun aburo won tii se oranmiyan,n ni oranmiyan pada so di isakole to ngba lowo awon ilu jilu ti awon egbon-on re ti tedo siwaju ti e,
Isakole gbigba di tipatipa fun oranmiyan eleyii to si di asa fun ilu oyo lati je gaba le awon opolopo ilu lori nile yoruba,isele isakole gbigba yii lo si je ki opolopo ilu nile yoruba so Alaafin di eru jeje,ki o to waa dipe awon oyinbo amunisin wo ile Yoruba,ti oko owo eru pada pare,ti isakole gbigba si nwa si opin.
Nitori akoko,ao fee fa itan naa gun lo t**i,

Ibeere pataki nipe,
1-Nje oseese ki ilu oyo gba ipo agba lowo Orirun re tii se ILU ILE IFE bi?

2-Ti ko ba wa seese fun ilu oyo lati je Orirun gbogbo ile Yoruba to si je pe Ile ife yii naa ni Orirun ilu oyo gan-an,nje Alaafin oyo gbodo maa ba ilu Ile ife jijagudu Ajulo?

3-Kinni ere ti awon oba Alaafin oyo ati Oonirisa to ti gbe'se ti je Lori fa nfa emi juo,Iwo kojumi fun Iran Yoruba lapapo bikonse ifaseyin?

4-Bi a ba ko ti ao sopin ote laarin ifi'ga gba'ga Alaafin oyo ati Oonirisa ki o to pe ju,nje awon Iran diran Yoruba ti nbo yoo le su're fun Iran yii ati awon ti o ti koja?

AWON AKIYESI GBOGBO IRAN YORUBA LORI ABUKU TO DE BA IPO OBA LAYE ODE ONI.

-Oselu ti wo'nu Ilana if'obaje nile yoruba ko je ki eto if'obaje duro DeeDee bii ti atijo.

-Awon oba alade gan n gbabode fun Iran Yoruba Nipa titori owo fini je oye

-Ifa ko fi oba je mo,Oselu lafi nmu oba nilee Yoruba laye ode Oni,ti ko si je ki ilee wa te siwaju

-Awon Oba aladee wa, nbe Fulani lowe lati baa sin maaluu, eyii ko si fun awon agbaagba ti won ti je dodo lanfaani lati Le so ododo

-Awon agbesunmomi ti won Ile Yoruba,emi awon eniyan ti ko se ti nsonu,
Awon oba alade ko ri kankan se sii,sebi laye igbakan,oba alade ni yoo pe awon ti oro kan lati Mo igbese to to ,ti aburu ko fi nii wo'nu ilu wa.

Ohun ti a mo ni pe Iran Yoruba kii se Arinfin,
Ki gbogbo abesinkawo si loo simedo,ki e je ki awon obaa wa pa okan po fi se ilu,ki won kuro nidii ifi'ga gba'ga to nso Iran Yoruba d'ero eyin,

A wa ko se gbe leyin enikeni,ki Ile Yoruba ma baje ni Egbe AJORO OMO ODUDUWA duro le l'ori.

Eku oju lona fun atejade Yoruba ronu apa keji lati owo Egbe AJORO OMO ODUDUWA.
(Registered)

Akiyesi -EGBE AJORO OMO ODUDUWA
Ko wa lati waa se'gbe leyin enikeni bi ko se lati waa fi ife ati isokan so Ile Yoruba po,
Aro gbogbo ojulowo omo (oko) Yoruba lati fi atejade yii s'owo si gbogbo ikanni to je ti omo Yoruba ni'le yii ati leyin odi.
Ile Yoruba ko nii daru oo.
(Aase)

Facebook -Ajoro omo oduduwa

What's app-
+234 813 4392 658

Email
✉️[email protected]

YORUBA CRADLE FESTIVAL 2025ODUN ISEDALE YORUBA 2025DATE-JULY 5TH 2025VENUE -DAVID AJIBOYE HALL,YINKA AYEFELE MUSIC HOUSE...
22/05/2025

YORUBA CRADLE FESTIVAL 2025

ODUN ISEDALE YORUBA 2025

DATE-JULY 5TH 2025
VENUE -DAVID AJIBOYE HALL,YINKA AYEFELE MUSIC HOUSE CHALLENGE IBADAN.

TIME -10:00AM

HOST- OLUAJORO ASIWAJU BABATUNDE BALOGUN JAGUNASO PEDEPEDE

CHIEF HOST- OMOWE JOEL OLA YINKA AYEFELE (OJA)

ROYAL FATHER OF THE DAY-
ALAYELUWA OBA ABDUL AKEEM OWO ADE ELEWU ETU 1(ALAAFIN OYO)

ANKARA WITH PASS-10K
AVAILABLE AT FRESH FM IBADAN
OR
CONTACT -HAMED ASIMIYU
IGOLOJU OLOWO ON
08061356891
TAIWO AK'OROIWOSI
Come, let's celebrate our cultural Heritage.

*Keeeereoooo*Eyii ni lati kede pe ipade pataki ti Egbe *AJORO OMO ODUDUWAYoo waye ni ori ayelujara what's app *Ojo*-Aje(...
16/03/2025

*Keeeereoooo*
Eyii ni lati kede pe ipade pataki ti Egbe *AJORO OMO ODUDUWA
Yoo waye ni ori ayelujara what's app
*Ojo*
-Aje(Monday )to nbo yii 17/03/2025
*Akoko*
-Agogo Mesan lale _(9:00pm_ )
*Aaye ipade*
-Yara isokan egbe AJORO OMO ODUDUWA _
_lori what's app egbe tuntun
- *Ede taolo lati se ipade*
- -Ede Yoruba ponbele
- Lati dara po mo egbe AJORO OMO ODUDUWA, ati lati kopa ni ipade naa
- Efi atejise"mo Fe darapo mo egbe AJORO OMO ODUDUWA"
*Sowo si Oluajoro Asiwaju Babatunde Balogun*
_(jagunaso pedepede_ )
*Lori-
+907 0577 719
_Ile Yoruba lapapo konii daru ooo.

*Keeeereoooo*Eyii ni lati kede pe ipade pataki ti Egbe *AJORO OMO ODUDUWAYoo waye ni ori ayelujara ninu Yara yii *Ojo*-E...
24/02/2025

*Keeeereoooo*
Eyii ni lati kede pe ipade pataki ti Egbe *AJORO OMO ODUDUWA
Yoo waye ni ori ayelujara ninu Yara yii
*Ojo*
-Eni ojo aje (Monday) gangan ni 24 /02/2025
*Akoko*
-Agogo Mejo abo lale _(8:30pm_ )
*Aaye ipade*
-Yara isokan egbe AJORO OMO ODUDUWA _
_lori what's app egbe tuntun
- *Ede taolo lati se ipade*
- -Ede Yoruba ponbele
- Lati dara po mo egbe AJORO OMO ODUDUWA, ati lati kopa ni ipade naa
- Efi atejise"mo Fe darapo mo egbe AJORO OMO ODUDUWA"
*Sowo si Oluajoro Asiwaju Babatunde Balogun*
_(jagunaso pedepede_ )
*Lori-
+907 0577 719
_Ile Yoruba lapapo konii daru ooo

A R O G U N OOO

Arojile baba iwa.....

Address

Association For Ajoro Omo Oduduwa(Headquarter) Ibadan
Ibadan

Telephone

+2348096653682

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Ajoro omo oduduwa posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Organization

Send a message to Ajoro omo oduduwa:

Share