Yoruba Public Library

Yoruba Public Library Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from Yoruba Public Library, Community Center, 1 Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park, London.

Yorùbá Public Library (Ilé ìyáwèé/kàwé gbogbogbòò Yorùbá) jẹ́ àkọ́kọ́ Ilé ìyáwèé/kàwé ajẹmọ́dííjìtì tó kó àkótán lórí Ìmọ̀ àti àṣà Yorùbá.Lára àwọn ohun tó sódo sínú náà rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ ajẹmọ́dííjìtì ni:Ìwádìí, agbo-ajẹmọ́ọ̀wé, ilé ìkówèé-pamọ́ sí

AṢỌ ILẸ̀ Yorùb: ÀMÌ ÌDÁNIMỌ̀ ÀTI ÀROKÒ AJẸMÁṢÀ / YORÙBÁ ATTIRE: A SYMBOL OF IDENTITY AND CULTURAL CODE Aṣọ wíwọ̀ jẹ àrok...
09/10/2026

AṢỌ ILẸ̀ Yorùb: ÀMÌ ÌDÁNIMỌ̀ ÀTI ÀROKÒ AJẸMÁṢÀ / YORÙBÁ ATTIRE: A SYMBOL OF IDENTITY AND CULTURAL CODE
Aṣọ wíwọ̀ jẹ àrokò ajẹmáṣà ní ilẹ̀ Yorùbá tó ń ṣàfihàn ipò àwùjọ, ọjọ́-orí àti ìmọ̀lára. Àwọn aṣọ ìbílẹ̀ bíi agbádá, ìró àti bùbá aṣọ òkè àti àdìrẹ ń ṣe àdáyanrí àwọn Yorùbá lásìkò ayẹyẹ. Àwọn ìdílé ọba/oyè àti àwọn àgbàlagbà máa ń wọ àwọn aṣọ tó jojú ní gbèsè pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ bíi ìlẹ̀kẹ̀ iyùn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ ìwọ́lẹ̀ jẹ́ alábọ́dé síbẹ̀ síbẹ̀ ó ń ṣàfihàn àṣà. Ìmúra máa ń mú kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún èèyàn pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àrà, awọ̀ fún onírúurú ayẹyẹ, ọ̀fọ̀ àti àjọyọ̀. Láìdéǹàpẹnu, aṣọ wíwọ́ Yorùbá tayọ oge ṣíṣe lásán ṣùgbọ́n ó ń ṣàfihàn ìṣe, ìṣẹ̀mbáyé àti ipò àwùjọ.

In Yorùbáland, dressing serves as a cultural code that reflects identity, social status, age, and even emotions. Traditional attire such as agbádá, ìró and bùbá, aso òkè, and adìrẹ distinguishes the Yorùbá people while also marking class and occasion. Royalty and elders wear more elaborate outfits with accessories like coral beads, while everyday wear is simpler but still culturally significant. Dressing also conveys respect and propriety, with styles and colors varying for ceremonies, mourning, and celebrations. Ultimately, Yorùbá dressing is not just fashion but a language of tradition, heritage, and social order.

📷 Wikipedia













ÀLÀYÉ ÒWE YORÙBÁ/YORÙBÁ PROVERB Aṣọ tí àlejò ní tó ń gan apá, onílé ní lábẹ́ àpótí, òde ni kò tíì kàn án ni.The attire a...
09/10/2026

ÀLÀYÉ ÒWE YORÙBÁ/YORÙBÁ PROVERB
Aṣọ tí àlejò ní tó ń gan apá, onílé ní lábẹ́ àpótí, òde ni kò tíì kàn án ni.

The attire a guest proudly dons in the presence of his host may be replicated in the host's own wardrobe, but is not presently required.

True worth isn't about external appearances!! Don't judge others based on appearances.

©Olabode Adekanye
📷telugluplex.com













ÀKỌTỌ́/ORTHOGRAPHY Fínní ni adìyẹ ń toko èèmọ́ bọ̀The hen walks through the burrs and comes out untouched.
07/10/2026

ÀKỌTỌ́/ORTHOGRAPHY
Fínní ni adìyẹ ń toko èèmọ́ bọ̀

The hen walks through the burrs and comes out untouched.










ÀKỌTỌ́/ORTHOGRAPHYFínní ni adìyẹ ń toko èèmọ́ bọ̀The hen walks through the burrs and comes out untouched.
07/10/2026

ÀKỌTỌ́/ORTHOGRAPHY
Fínní ni adìyẹ ń toko èèmọ́ bọ̀

The hen walks through the burrs and comes out untouched.










OÚNJẸ ILẸ̀ WA/OUR NATIVE FOOD Àbàrí jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ aládùn tí wọ́n fi àgbàdo ṣe, ìgbésẹ̀ sísè rẹ̀ farapẹ́ ọ̀ọ̀lẹ̀. Àwọn...
05/10/2026

OÚNJẸ ILẸ̀ WA/OUR NATIVE FOOD
Àbàrí jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ aládùn tí wọ́n fi àgbàdo ṣe, ìgbésẹ̀ sísè rẹ̀ farapẹ́ ọ̀ọ̀lẹ̀. Àwọn èròjà láti fi se e ni àgbàdo, ata rodo, tàtàṣé, àlùbọ́sà, epo tàbí òróró, iyọ̀, amọ́bẹ̀dùn, omi tó lọ́wọ́rọ́ (ẹyin, ẹran tàbí ẹja jíjá - èyí kò pọn dandan. Wọ́n ń fi àbàrí jẹ ẹ̀kọ, búrẹ́dì, ògì tàbí gààrí.

Àbàrí is a traditional delicacy made with corn and prepared exactly like moinmoin. The ingredients in preparing Àbàrí are corn, rodo, tàtàṣé, onions, vegetable or palm oil, salt, maggi, warm water, (eggs, mashed fish/meat -optional). Àbàrí can be eaten with ẹ̀kọ, bread, ògì or gààrí.

Picture Credit: foodnify











Ojúmọ́ore ló mọ́ wa lónìí! It is a beautiful morning!
05/10/2026

Ojúmọ́ore ló mọ́ wa lónìí!
It is a beautiful morning!











A kú ojúmọ́ òní ẹyin èèyàn wa gbogbo! Good morning beautiful people!
04/10/2026

A kú ojúmọ́ òní ẹyin èèyàn wa gbogbo!
Good morning beautiful people!











ÒWE YORÙBÁ/YORÙBÁ PROVERB Ọ̀gá ni aáyán tó ń wọṣọ mẹ́fà papọ̀, ìhòòhò kúkú ni aláǹtakùn tó ń fi ojoojúmọ́ ran òwú wà. Th...
03/10/2026

ÒWE YORÙBÁ/YORÙBÁ PROVERB
Ọ̀gá ni aáyán tó ń wọṣọ mẹ́fà papọ̀, ìhòòhò kúkú ni aláǹtakùn tó ń fi ojoojúmọ́ ran òwú wà.

The cockroach that wears six layers of clothing is indeed a remarkable creature, while the spider, despite weaving tirelessly every day, remains completely unclothed.











ÀWỌN ÌPÁPÁNU YORÙBÁ/ YORÙBÁ SNACKS Àwọn ìpápánu Yorùbá ládùn wọ́n sì wà ní onírúurú láti ṣe àfihàn pàtàkì àjogúnbá oúnjẹ...
02/10/2026

ÀWỌN ÌPÁPÁNU YORÙBÁ/ YORÙBÁ SNACKS
Àwọn ìpápánu Yorùbá ládùn wọ́n sì wà ní onírúurú láti ṣe àfihàn pàtàkì àjogúnbá oúnjẹ síse/iná dídá. Díẹ̀ lára àwọn ìpápánu Yorùbá ti ó gbajúmọ̀ nì wọ̀nyí:róbó, àkàrà, ìpékeré, kókóró, àádùn, dòdò ìkirè, dùn-ùn-dún, bọ̀lì, gúgúrú, ẹ̀pà yíyan, àgbàdo sísun abbl. Àǹfààní àwọn ìpápánu yìí tayọ adùn lásán torí pàtàkì ajẹmáṣà àti ajẹmẹ́sìn wọn ní ìpejọ àwùjọ àti ayẹyẹ.

Yorùbá snacks are delicious and diverse reflecting the rich culinary heritage of the Yorùbá people. Here are some of the popular Yorùbá snacks: róbó, àkàrà, ìpékeré, kókóró, àádùn, dòdò ìkirè, dùn-ùn-dún, bọ̀lì, gúgúrú, ẹ̀pà yíyan, àgbàdo sísun etc. These snacks are not only delicious but also rich in cultural and religious significance often served at social gatherings and celebrations.












Ìlànà ìmọ̀ èrò ìjìnlẹ̀ ìbílẹ̀ Yorùbá ti dé ìpele tó níyelórí nítorí ìlànà ètò àwùjọ tó ṣe é dáradé fún òmìnira, àlàáfíà,...
01/10/2026

Ìlànà ìmọ̀ èrò ìjìnlẹ̀ ìbílẹ̀ Yorùbá ti dé ìpele tó níyelórí nítorí ìlànà ètò àwùjọ tó ṣe é dáradé fún òmìnira, àlàáfíà, ìdúóore, òfin àti ìlànà ni.

The Yorùbá traditional philosophy has reached a remarkable level because of the social structure which is a guarantee of freedom, peace, stability, law and order.

Ìtọ́kasí: Iṣẹ́ Ọ̀kẹ́wándé Olúwòlé nínú Jónà Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Yorùbá
📷 Pinterest











Address

1 Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park
London
N77PH

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Yoruba Public Library posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The Organisation

Send a message to Yoruba Public Library:

Shortcuts

Share