Gbigbe Ede Ati Asa Yoruba Laruge Pada

  • Home
  • Gbigbe Ede Ati Asa Yoruba Laruge Pada

Gbigbe Ede Ati Asa Yoruba Laruge Pada Gbigbe Ede ati asa Yoruba laruge pada

20/03/2026
20/03/2026





ÌTÀN 49: Ọba tí o ma fi àìní sùúrù àti ìrunú ṣe ìdájọ́.Ní ìlú kan, ọba kan wà tí gbogbo ènìyàn fẹ́ràn. Ṣùgbọ́n ọjọ́ kan,...
13/03/2026

ÌTÀN 49: Ọba tí o ma fi àìní sùúrù àti ìrunú ṣe ìdájọ́.
Ní ìlú kan, ọba kan wà tí gbogbo ènìyàn fẹ́ràn. Ṣùgbọ́n ọjọ́ kan, ìjà kan ṣẹlẹ̀ nínú ìlú, ó sì fa wàhálà àti ìbànújẹ́ sí ilé ọba náà.
Ọba bínú gidigidi. Ní ìbànújẹ́ àti àìní sùúrù ọba
Pẹ̀lú ìrunú ọba dá ẹjọ́ náà kalẹ̀ pẹ̀lú iná dídá láti fi jó àwọn ẹrú tí ó da ìjà sílẹ̀, le ju bó ṣe yẹ lọ.
Ọ̀pọ̀ ará ìlú jìyà torí ìbínú ọba àti ẹjọ́ dídá yìí bá àwọn nkan alumọni ìlú jẹ́.
Àgbà kan wá sọ fún un ọba pé:
“Kabiyesi, ìdájọ́ nínú ìbínú kì mú èso rere lọwọ.”
Ọba jókòó, ó ronú pẹ́. Ó mọ̀ pé ìpinnu tí a bá ṣe nínú ìbínú lè fa ìbànújẹ́ pẹ̀lú.

Ó pe gbogbo ará ìlú jọ, ó sì yí àwọn ìlànà padà.

Lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, ọba kọ́ pé ìjọba kì í ṣe pẹ̀lú ìbínú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ̀ àti ọgbọ́n.

Ẹ̀kọ́ ìwà:
✔ Ìpinnu nínú ìbínú lè ba ìjọba jẹ.

✔ Ọba rere ń ronú kí ó tó dá ìdájọ́.
Fẹ́ràn (like)
Pin kárí (share)
Tẹ̀lé wa (follow)
Adúpẹ́.

13/03/2026

Ìyá adìe ti o nfi gbogbo ọmọ rẹ ṣere





ÌTÀN 48: Ọba àti Agbẹ talakàNí ìlú kan, àgbẹ̀ tálákà kan wà tí ilẹ̀ rẹ̀ ń ni ọ̀rá Púpọ̀ gan-an. Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìfárabalẹ̀...
11/03/2026

ÌTÀN 48: Ọba àti Agbẹ talakà
Ní ìlú kan, àgbẹ̀ tálákà kan wà tí ilẹ̀ rẹ̀ ń ni ọ̀rá Púpọ̀ gan-an.
Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìfárabalẹ̀ àti sùúrù. Ọjọ́ kan, ọba gbọ́ pé àgbẹ̀ náà ń rí àṣeyọrí, ó sì pè wa sí ààfin.
Ní ìpàdé náà, ọba béèrè pé:
“Kí ni awọn ohun tí, ohun lò tí o fi ń ṣiṣẹ oko ti ilẹ̀ rẹ̀ fi ní ọ̀rá gidi nínú?”
Àgbẹ̀ náà dá a lóhùn pé:
“Kabiyesi, mo máa ń bọ̀wọ̀ fún ilẹ̀, mo sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú sùúrù.”
Ọba rí i pé àgbẹ̀ náà kò ní ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ó ní ìfaradà àti ìmọ̀.
Dípò kí ọba gba ilẹ̀ àgbẹ̀ náà lọ́wọ́ rẹ̀ bí àwọn olóyè kan ṣe daba, ọba pinnu láti kọ́ àwọn àgbẹ̀ míì pẹ̀lú ìmúlò rẹ̀.
Ní kẹ́yìn, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí í rí àṣeyọrí.
Ọba sọ pé:
“Ọlọ́rọ̀ kì í ṣe ẹni tí ó ní owó nìkan; ṣugbọn ẹni tí ó ní ọgbọ́n ninu pẹ̀lú.”
Ẹ̀kọ́ ìwà:
✔ Ọgbọ́n àti sùúrù ni ń mú ìbùkún wá.

✔ Ọba rere ń gbé ará ìlú rẹ̀ ga, kì í ṣe kó wọn lulẹ̀.
Fẹ́ràn (like)
Pin kárí (share)
Tẹ̀lé wa (follow)
Adúpẹ́.

11/03/2026

Ọmọ Tí Kò Fetí Sí Ítọnisónà Àgbà





ÌTÀN 47: Ọba tí ó fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.Ní ìlú kan, ọba kan wà tí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ òtítọ́ tí ó le dun ju irọ lọ....
09/03/2026

ÌTÀN 47: Ọba tí ó fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.
Ní ìlú kan, ọba kan wà tí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ òtítọ́ tí ó le dun ju irọ lọ.
Ní gbogbo ìpàdé ààfin, bí ẹnikẹ́ni bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ òtítọ́ fún ojú rẹ yóò korò inú rẹ yóò sì bàjẹ́ gidigidi.
ọba yóò sì dá ẹni náà dúró kí o ma le tèsíwájú ọ̀rọ̀ náà mọ
Ó máa ń sọ pé:
“Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí ń yo mu inú mí dun, koda bí mo bá ṣe aṣiṣe,ko sì Eniti o tọ́ sí láti sọ funmi.
Díẹ̀díẹ̀, gbogbo olóyè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ó yóò máa mú inú ọba dùn ní etí ọba.
Ṣùgbọ́n nínú ìlú, ìṣòro àti ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀, wàhálà àti laasigbo wa, àwọn ará ìlú sì ń jìyà.
Ọjọ́ kan, àjàkálẹ̀ ààrùn kan dé bá ìlú. Nígbà tí ọba béèrè pé:
“Kí ló ṣẹlẹ̀?”
Kò sí ẹni tí ó sọ ìdí gangan tàbí ọ̀nà abayọ fún ọba nitorí pé ọba kò fẹ otitọ rárá.
Ṣe Yorùbá ni irọ́ kúta l'ọja ọ di otitọ.
Àwọn ará ìlú ṣe ìtọ́jú ara wọn láì sọ fún ọba ọ̀nà abayọ fún ọba.
Ọba wa ri wipe kí a sọ òtítọ́ fún ní tí o dun ni,o San ju ki a má tàn nilọ.
Ọba sì rí ara rẹ he fún àtúnṣe.
Ẹ̀kọ́ ìwà:
✔ Òtítọ́ tó dun ju irọ́ lọ bi o tilẹ̀ má dùn ní gan,sùgbọ́n ọ ma mú ayọ wá nigbeyin.

✔ Ọba tí o kọ òtítọ́, ìtẹ́ ko ni duro pẹ́.
Fẹ́ràn (like)
Pin kárí (share)
Tẹ̀lé wa (follow)
Adúpẹ́.

09/03/2026

Ajá Tí Kò Dúpẹ́





ÌTÀN 46: Ọba tí kò mọ̀ pé agbára àti àdéhùn yàtọ̀.Ní ìjọba kan, ọba kan wà tí ó rò pé agbára rẹ̀ jẹ́ ohun tí kò le yí pa...
06/03/2026

ÌTÀN 46: Ọba tí kò mọ̀ pé agbára àti àdéhùn yàtọ̀.
Ní ìjọba kan, ọba kan wà tí ó rò pé agbára rẹ̀ jẹ́ ohun tí kò le yí padà. Ó máa ń sọ pé:
“Ìtẹ́ yìí jẹ́ ti temi títí láé.”
Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpinnu láì kàn sí ará ìlú. Bí ẹnikẹ́ni bá kùn tàbí sọ̀rọ̀, ó máa ń dá wọn lẹ́bi pé kò bọ̀wọ̀ fún ìtẹ́.
díẹ̀díẹ̀, ará ìlú bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó sí ààyè wọn,
Wọn sì kojú mọ iṣẹ wọn, nitori iṣẹ́ lògùn ìṣẹ́, ilọsiwaju dé bá ilé ẹnìkọ̀kan wọn, láì farawé ọba.
Ọjọ́ kan, àgbà ìlú kan sọ fún ọba pé:
“Kabiyesi, agbára kì í ṣe ohun tí ọba ní lo, láti lò lórí ọmọ ìlú,àdéhùn si jẹ awọn ileri láàárín ọba àti ará ìlú, ohun meji ti ko sì jọ ra wọn ni.”
Ọba sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àgbà ìlú náà,ọ sí wọnú ìyẹ̀wù rẹ lọ
Lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, ó ṣe ìlànà tuntun tí yóò mú kí ará ìlú ní ohùn nínú ìpinnu àti àdéhùn ìlú lápapọ̀ láì ṣi agbára lo.
Ẹ̀kọ́ ìwà:
✔ Agbára kí se àdéhùn, kì í ṣe ohun tí a jogún nìkan.

✔ Ọba àti ará ìlú gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀.
Fẹ́ràn (like)
Pin kárí (share)
Tẹ̀lé wa (follow)
Adúpẹ́.

ÌTÀN 45: Ọba àti tálákà ọmọ ará ìlú tí o mọ iṣẹ àsekára ṣe.Ní ìlú kan, ará ìlú talakà kan wà tí ó mọ iṣẹ àṣekára ṣe púpọ...
04/03/2026

ÌTÀN 45: Ọba àti tálákà ọmọ ará ìlú tí o mọ iṣẹ àsekára ṣe.
Ní ìlú kan, ará ìlú talakà kan wà tí ó mọ iṣẹ àṣekára ṣe púpọ̀.
Ó ń ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí o mọyì iṣẹ ti o nse ,o sí ní ọgbọ̀n àti sọ iṣẹ kékeré di ni nla.
Ọjọ́ kan, ọmọ ará ìlú tálákà náà wá sí ààfin, ó ní:
“Kabiyesi, mo ní èrò kan tí yóò mú ìlú wa dàgbà.”
Àwọn olóyè rẹ́rìn-ín, wọ́n sọ pé:
“Ta ni ìwọ tí yóò kọ́ ọba?”
Ṣùgbọ́n ọba pinnu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. ọmọ Ará ìlú tálákà náà ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè tún ọjà ṣe kí ìṣòwò lè pọ̀ sí i.
Ọba gba èrò náà, wọ́n sì ṣe àtúnṣe. Ní kẹ́yìn, ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí í lágbára ju tẹ́lẹ̀ lọ.
Ọrọ̀ ajé ìlú náà rú gọ́gọ́ sókè gidi gan, inú ọba dùn.
Ọba pè gbogbo awọn ìjòyè àti ènìyàn jọ, ó sì sọ pé:
“Ọgbọ́n kì tí inú ààfin nìkan wà o pe awọn olóyè àti gbogbo ará ìlú sí àkíyèsí.”
O si daa ọmọ tálákà náà àti ẹbí rẹ lọ́lá rẹpẹtẹ.
Látì ọjọ́ yẹn lọ, àwọn ìjòyè áti gbogbo ará ìlú kọ́gbọ́n wípé kò sí ẹnití Elédùmárè kò lè lo,láìka ipo wọn sí.
Ẹ̀kọ́ ìwà:
✔ Ọgbọ́n lè wà lọ́dọ̀ ẹni kékeré.

✔ Ọba tó gbọ́ ohùn gbogbo ènìyàn, ni ìlú rẹ̀ máa ń lágbára.
Fẹ́ràn (like)
Pin kárí (share)
Tẹ̀lé wa (follow)
Adúpẹ́.

Address


Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Gbigbe Ede Ati Asa Yoruba Laruge Pada posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

  • Want your organization to be the top-listed Non Profit Organization?

Share